ORIKI IBADAN
OMO IBADAN KIN NI SOOO RE?Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun. Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.